Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 16:12-22 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nígbà tí ó dára fún mi,ó fi ẹ̀yìn mi wọ́nlẹ̀,ó fún mi lọ́rùn, ó gbé mi ṣánlẹ̀,ó sì gbọ̀n mí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́;ó yàn mí sọjú bí àmì ìtafà sí.

13. Àwọn tafàtafà rẹ̀ yí mi ká,ó la kíndìnrín mi láìṣàánú mi,ó sì tú òróòro mi jáde.

14. Ó ń gbógun tì mí nígbà gbogbo,ó pakuuru sí mi bí ọmọ ogun.

15. “Mo fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara,mo sùn gbalaja sinu erùpẹ̀.

16. Mo sọkún títí ojú mi fi pọ́n,omijé sì mú kí ojú mi ṣókùnkùn,

17. bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ibi,adura mi sì mọ́.

18. “Ìwọ ilẹ̀, má ṣe bo ẹ̀jẹ̀ mi mọ́lẹ̀,má sì jẹ́ kí igbe mi já sí òfo.

19. Nisinsinyii, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ lọ́run,alágbàwí mi sì ń bẹ lókè.

20. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,mo sì ń sọkún sí Ọlọrun,

21. ìbá ṣe pé ẹnìkan lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọrun,bí eniyan ti lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀ níwájú eniyan.

22. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ sí i,n óo lọ àjò àrèmabọ̀.

Ka pipe ipin Jobu 16