Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 16:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jobu bá dáhùn pé,

2. “Èmi náà ti gbọ́ irú nǹkan wọnyi rí,ọlọ́rọ̀ ìtùnú kòbákùngbé ni gbogbo yín.

3. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ yìí tilẹ̀ lópin?Àbí, kí ní ń fa gbogbo àríyànjiyàn yìí?

4. Bí ẹ bá wà ní ipò mi,èmi náà lè sọ̀rọ̀ bí ẹ tí ń sọ̀rọ̀ yìí,kí n da ọ̀rọ̀ bò yín,kí n sì máa mi orí si yín.

5. Mo lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fun yín lókun,kí ọ̀rọ̀ ìtùnú mi sì mú kí ara tù yín.

6. “Bí mo sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ kò mú kí ara tù mí,bí mo bá sì dákẹ́, ṣé dídákẹ́ lè tán ìrora mi?

7. Dájúdájú Ọlọrun ti dá mi lágara,ó ti sọ gbogbo ilé mi di ahoro.

8. Híhunjọ tí ara mi hunjọ, jẹ́ ẹ̀rí láti ta kò mí;rírù tí mo rù ta àbùkù mi,ó sì hàn lójú mi.

9. Ó ti fi ibinu fà mí ya,ó sì kórìíra mi;ó pa eyín keke sí mi;ọ̀tá mi sì ń fojú burúkú wò mí.

10. Àwọn eniyan ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,wọ́n ń gbá mi létí,wọ́n kó ara wọn jọ sí mi.

11. Ọlọrun fà mí lé eniyan burúkú lọ́wọ́,ó mú kí n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ìkà.

Ka pipe ipin Jobu 16