Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 15:26-35 BIBELI MIMỌ (BM)

26. ó ń ṣe oríkunkun sí i,ó sì gbé apata tí ó nípọn lọ́wọ́ láti bá a jà;

27. nítorí pé ó sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú rẹ̀ yíbò,ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ kìkì ọ̀rá.

28. Ó ń gbé ìlú tí ó ti di ahoro,ninu àwọn ilé tí eniyan kò gbọdọ̀ gbé,àwọn ilé tí yóo pada di òkítì àlàpà.

29. Kò ní ní ọrọ̀,ohun tí ó bá ní, kò ní pẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,òun alára kò sì ní fìdí múlẹ̀.

30. Kò ní bọ́ kúrò ninu òkùnkùn,iná yóo jó àwọn ẹ̀ka rẹ̀,afẹ́fẹ́ yóo sì fẹ́ àwọn ìtànná rẹ̀ dànù.

31. Kí ó má gbẹ́kẹ̀lé òfo,kí ó má máa tan ara rẹ̀ jẹ,nítorí òfo ni yóo jẹ́ èrè rẹ̀.

32. A ó san án fún un lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lọ́jọ́ àìpé,gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ ni yóo sì gbẹ.

33. Yóo gbọn àwọn èso rẹ̀ tí kò tíì pọ́n dànù, bí àjàrà,yóo sì gbọn àwọn ìtànná rẹ̀ dànù, bí igi olifi.

34. Nítorí asán ni àwùjọ àwọn tí wọn kò mọ Ọlọ́run,iná yóo sì jó ilé àwọn tí ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

35. Wọ́n ń ro èrò ìkà,wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi,wọ́n sì ń pète ẹ̀tàn lọ́kàn.”

Ka pipe ipin Jobu 15