Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 15:19-33 BIBELI MIMỌ (BM)

19. àwọn nìkan ni a fún ní ilẹ̀ náà,àlejò kankan kò sì sí láàrin wọn).

20. Ẹni ibi ń yí ninu ìrora ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,àní, ní gbogbo ọdún tí a là sílẹ̀ fún ìkà.

21. Etí rẹ̀ kún fún igbe tí ó bani lẹ́rù,ninu ìdẹ̀ra rẹ̀ àwọn apanirun yóo dìde sí i.

22. Kò gbàgbọ́ pé òun lè jáde kúrò ninu òkùnkùn;ati pé dájú, ikú idà ni yóo pa òun.

23. Ó ń wá oúnjẹ káàkiri, ó ń bèèrè pé,‘Níbo ló wà?’Òun gan-an sì nìyí, oúnjẹ àwọn igún!Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn ti súnmọ́ tòsí.

24. Ìdààmú ati ìrora dẹ́rùbà á,wọ́n ṣẹgun rẹ̀, bí ọba tí ó múra ogun.

25. Nítorí pé ó ṣíwọ́ sókè sí Ọlọrun,o sì ṣe oríkunkun sí Olodumare,

26. ó ń ṣe oríkunkun sí i,ó sì gbé apata tí ó nípọn lọ́wọ́ láti bá a jà;

27. nítorí pé ó sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú rẹ̀ yíbò,ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ kìkì ọ̀rá.

28. Ó ń gbé ìlú tí ó ti di ahoro,ninu àwọn ilé tí eniyan kò gbọdọ̀ gbé,àwọn ilé tí yóo pada di òkítì àlàpà.

29. Kò ní ní ọrọ̀,ohun tí ó bá ní, kò ní pẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,òun alára kò sì ní fìdí múlẹ̀.

30. Kò ní bọ́ kúrò ninu òkùnkùn,iná yóo jó àwọn ẹ̀ka rẹ̀,afẹ́fẹ́ yóo sì fẹ́ àwọn ìtànná rẹ̀ dànù.

31. Kí ó má gbẹ́kẹ̀lé òfo,kí ó má máa tan ara rẹ̀ jẹ,nítorí òfo ni yóo jẹ́ èrè rẹ̀.

32. A ó san án fún un lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lọ́jọ́ àìpé,gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ ni yóo sì gbẹ.

33. Yóo gbọn àwọn èso rẹ̀ tí kò tíì pọ́n dànù, bí àjàrà,yóo sì gbọn àwọn ìtànná rẹ̀ dànù, bí igi olifi.

Ka pipe ipin Jobu 15