Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 13:5-21 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ẹ̀ bá jẹ́ pa ẹnu yín mọ́ ni,à bá pè yín ní ọlọ́gbọ́n!

6. Nisinsinyii ẹ gbọ́ èrò ọkàn mi,kí ẹ sì fetísí àròyé mi.

7. Ṣé ẹ óo máa parọ́ ní orúkọ Ọlọrun ni,kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní orúkọ rẹ̀?

8. Ṣé ẹ fẹ́ máa ṣe ojuṣaaju fún Ọlọrun ni?Tabi ẹ fẹ́ jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀?

9. Ṣé ẹ óo yege bí ó bá dán yín wò?Tabi ẹ lè tan Ọlọrun bí ẹni tan eniyan?

10. Dájúdájú, yóo ba yín wí,bí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju níkọ̀kọ̀.

11. Ògo rẹ̀ yóo dẹ́rùbà yín,jìnnìjìnnì rẹ̀ yóo dà bò yín.

12. Àwọn òwe yín kò wúlò,àwíjàre yín kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

13. Ẹ dákẹ́, kí n ráyè sọ tèmi,kí ohun tí yóo bá dé bá mi dé bá mi.

14. N óo dijú, n óo fi ẹ̀mí ara mi wéwu.

15. Wò ó, yóo pa mí; n kò ní ìrètí;sibẹ n óo wí àwíjàre tèmi níwájú rẹ̀.

16. Èyí ni yóo jẹ́ ìgbàlà mi,nítorí pé ẹni tí kò mọ Ọlọrun,kò ní lè dúró níwájú rẹ̀.

17. Fetí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi,kí o sì gbọ́ mi ní àgbọ́yé.

18. Wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀;mo sì mọ̀ pé n óo gba ìdáláre.

19. Ta ni yóo wá bá mi rojọ́?Bí ó bá wá, n óo dákẹ́, n óo sì kú.

20. Nǹkan meji péré ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi,n kò sì ní farapamọ́ fún ọ:

21. ká ọwọ́ ibinu rẹ kúrò lára mi,má sì ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì rẹ dà bò mí.

Ka pipe ipin Jobu 13