Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 13:17-26 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Fetí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi,kí o sì gbọ́ mi ní àgbọ́yé.

18. Wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀;mo sì mọ̀ pé n óo gba ìdáláre.

19. Ta ni yóo wá bá mi rojọ́?Bí ó bá wá, n óo dákẹ́, n óo sì kú.

20. Nǹkan meji péré ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi,n kò sì ní farapamọ́ fún ọ:

21. ká ọwọ́ ibinu rẹ kúrò lára mi,má sì ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì rẹ dà bò mí.

22. Lẹ́yìn náà, sọ̀rọ̀, n óo sì fèsì;tabi kí o jẹ́ kí èmi sọ̀rọ̀, kí o sì fún mi lésì.

23. Báwo ni àìdára ati ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ tó?Jẹ́ kí n mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati ibi tí mo ti kọjá ààyè mi.

24. Kí ló dé tí o fi fi ara pamọ́ fún mití o kà mí kún ọ̀tá rẹ?

25. Ṣé o óo máa dẹ́rùba ewé lásán tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri,tabi o óo máa lépa ìyàngbò gbígbẹ?

26. O ti kọ àkọsílẹ̀ burúkú nípa mi,o mú mi jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi.

Ka pipe ipin Jobu 13