1. “Gbogbo ìwọ̀nyí ni ojú mi ti rí rí,tí etí mi ti gbọ́, tí ó sì yé mi.
2. Ohun tí ẹ mọ̀ wọnyi, èmi náà mọ̀ ọ́n,ẹ kò sàn jù mí lọ.
3. Ṣugbọn n óo bá Olodumare sọ̀rọ̀,Ọlọrun ni mo sì fẹ́ bá rojọ́.
4. Ẹ̀yin òpùrọ́ ati ẹlẹ́tàn wọnyi,ẹ̀yin oníṣègùn tí ẹ kò lè wonisàn.
5. Ẹ̀ bá jẹ́ pa ẹnu yín mọ́ ni,à bá pè yín ní ọlọ́gbọ́n!
6. Nisinsinyii ẹ gbọ́ èrò ọkàn mi,kí ẹ sì fetísí àròyé mi.
7. Ṣé ẹ óo máa parọ́ ní orúkọ Ọlọrun ni,kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní orúkọ rẹ̀?
8. Ṣé ẹ fẹ́ máa ṣe ojuṣaaju fún Ọlọrun ni?Tabi ẹ fẹ́ jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀?
9. Ṣé ẹ óo yege bí ó bá dán yín wò?Tabi ẹ lè tan Ọlọrun bí ẹni tan eniyan?
10. Dájúdájú, yóo ba yín wí,bí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju níkọ̀kọ̀.
11. Ògo rẹ̀ yóo dẹ́rùbà yín,jìnnìjìnnì rẹ̀ yóo dà bò yín.
12. Àwọn òwe yín kò wúlò,àwíjàre yín kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
13. Ẹ dákẹ́, kí n ráyè sọ tèmi,kí ohun tí yóo bá dé bá mi dé bá mi.