14. Ohun tí Ọlọrun bá wó lulẹ̀,ta ló lè tún un kọ́?Tí ó bá ti eniyan mọ́lé,ta ló lè tú u sílẹ̀?
15. Bí ó bá dáwọ́ òjò dúró, ọ̀gbẹlẹ̀ a dé,bí ó bá sí rọ òjò, omi a bo ilẹ̀.
16. Òun ló ni agbára ati ọgbọ́n,òun ló ni ẹni tí ń tan ni jẹ,òun náà ló ni ẹni tí à ń tàn.
17. Ó pa ọgbọ́n mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu,ó sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.
18. Ó tú àwọn tí àwọn ọba dè mọ́lẹ̀,ó sì so ẹ̀wọ̀n mọ́ àwọn ọba gan-an nídìí.
19. Ó rẹ àwọn alufaa sílẹ̀,ó sì gba agbára lọ́wọ́ àwọn alágbára.
20. Ó pa àwọn agbẹnusọ lẹ́nu mọ́,ó gba ìmọ̀ àwọn àgbààgbà.
21. Ó dójúti àwọn olóyè,ó tú àmùrè àwọn alágbára.
22. Ó mú ohun òkùnkùn wá sí ìmọ́lẹ̀,ó sì tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn biribiri.
23. Òun níí sọ àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá,òun náà níí sìí tún pa wọ́n run:Òun níí kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ,òun náà níí sì ń tú wọn ká.
24. Ó gba ìmọ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjòyè ní gbogbo ayé,ó sì sọ wọ́n di alárìnká ninu aṣálẹ̀,níbi tí ọ̀nà kò sí.
25. Wọ́n ń táràrà ninu òkùnkùn,ó sì mú kí wọ́n máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí.