Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 12:10-21 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ọwọ́ rẹ̀ ni ìyè gbogbo ẹ̀dá wà,ati ẹ̀mí gbogbo eniyan.

11. Ṣebí etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,ahọ́n a sì máa tọ́ oúnjẹ wò?

12. “Àgbà ló ni ọgbọ́n,àwọn ogbó tí wọ́n ti pẹ́ láyé ni wọ́n ni òye.

13. Ọlọrun ló ni ọgbọ́n ati agbára,tirẹ̀ ni ìmọ̀ràn ati ìmọ̀.

14. Ohun tí Ọlọrun bá wó lulẹ̀,ta ló lè tún un kọ́?Tí ó bá ti eniyan mọ́lé,ta ló lè tú u sílẹ̀?

15. Bí ó bá dáwọ́ òjò dúró, ọ̀gbẹlẹ̀ a dé,bí ó bá sí rọ òjò, omi a bo ilẹ̀.

16. Òun ló ni agbára ati ọgbọ́n,òun ló ni ẹni tí ń tan ni jẹ,òun náà ló ni ẹni tí à ń tàn.

17. Ó pa ọgbọ́n mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu,ó sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.

18. Ó tú àwọn tí àwọn ọba dè mọ́lẹ̀,ó sì so ẹ̀wọ̀n mọ́ àwọn ọba gan-an nídìí.

19. Ó rẹ àwọn alufaa sílẹ̀,ó sì gba agbára lọ́wọ́ àwọn alágbára.

20. Ó pa àwọn agbẹnusọ lẹ́nu mọ́,ó gba ìmọ̀ àwọn àgbààgbà.

21. Ó dójúti àwọn olóyè,ó tú àmùrè àwọn alágbára.

Ka pipe ipin Jobu 12