Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 10:8-20 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ọwọ́ rẹ ni o fi dá mi,ọwọ́ kan náà ni o sì tún fẹ́ fi pa mí run.

9. Ranti pé, amọ̀ ni o fi mọ mí,ṣé o tún fẹ́ sọ mí di erùpẹ̀ pada ni?

10. Ṣebí ìwọ ni o dà mí bí omi wàrà,tí o sì ṣù mí pọ̀ bíi wàrà sísè?

11. Ìwọ ni o fi awọ ati ẹran bò mí,tí o rán egungun ati iṣan mi pọ̀.

12. O fún mi ní ìyè,o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi,ìtọ́jú rẹ sì ti gbé ẹ̀mí mi ró.

13. Sibẹ o pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́ sọ́kàn rẹ,mo mọ̀ pé èrò ọkàn rẹ ni pé,

14. bí mo bá ṣẹ̀, o óo dójú lé mi,o kò ní jẹ́ kí n lọ láìjìyà.

15. Bí mo bá ṣe àìdára, mo gbé,ṣugbọn bí mo ṣe dáradára, n kò lè yangàn,nítorí ìbànújẹ́ ati ìtìjú bò mí mọ́lẹ̀.

16. Bí mo bá ṣe àṣeyọrí,o óo máa lépa mi bíi kinniun;ò ń lo agbára rẹ láti pa mí lára.

17. O wá àwọn ẹlẹ́rìí tuntun pé kí wọ́n dojú kọ mí,O tún bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí mi lọpọlọpọ,O mú kí ogun mìíràn dó tì mí.

18. “Kí ló dé tí o fi mú mi jáde láti inú ìyá mi?Ìbá sàn kí n ti kú,kí ẹnikẹ́ni tó rí mi.

19. Wọn ìbá má bí mi rárá,kí wọ́n gbé mi láti inú ìyá mi lọ sinu ibojì.

20. Ṣebí ọjọ́ díẹ̀ ni mo níláti lò láyé?Fi mí sílẹ̀ kí n lè ní ìtura díẹ̀,

Ka pipe ipin Jobu 10