Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 10:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ayé sú mi,nítorí náà n kò ní dákẹ́ ìráhùn;n óo sọ̀rọ̀ pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn.

2. N óo sọ fún Ọlọrun pékí ó má dá mi lẹ́bi;kí ó sì jẹ́ kí n mọ ìdítí ó fi ń bá mi jà.

3. Ṣé ohun tí ó dára ni, Ọlọrunpé kí o máa ni eniyan lára,kí o kórìíra iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,kí o sì fẹ́ràn ète ẹni ibi?

4. Ǹjẹ́ ojú rẹ dàbí ti eniyan?Ǹjẹ́ a máa rí nǹkan bí eniyan ṣe rí i?

5. Ǹjẹ́ bí ọjọ́ ti eniyan ni ọjọ́ rẹ rí?Ǹjẹ́ ọdún rẹ rí bíi ti eniyan?

6. Tí o fi wá ń wádìí àṣìṣe mi,tí o sì ń tanná wá ẹ̀ṣẹ̀ mi?

7. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ pé n kò lẹ́bi,ati pé kò sí ẹnikẹ́nití ó lè gbà mí lọ́wọ́ rẹ.

8. Ọwọ́ rẹ ni o fi dá mi,ọwọ́ kan náà ni o sì tún fẹ́ fi pa mí run.

9. Ranti pé, amọ̀ ni o fi mọ mí,ṣé o tún fẹ́ sọ mí di erùpẹ̀ pada ni?

10. Ṣebí ìwọ ni o dà mí bí omi wàrà,tí o sì ṣù mí pọ̀ bíi wàrà sísè?

11. Ìwọ ni o fi awọ ati ẹran bò mí,tí o rán egungun ati iṣan mi pọ̀.

12. O fún mi ní ìyè,o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi,ìtọ́jú rẹ sì ti gbé ẹ̀mí mi ró.

Ka pipe ipin Jobu 10