Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 1:14-22 BIBELI MIMỌ (BM)

14. iranṣẹ kan wá sọ́dọ̀ Jobu, ó ròyìn fún un pé, “Àwọn akọ mààlúù ń fi àjàgà wọn kọlẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹko nítòsí wọn;

15. àwọn ará Sabea rí wọn, wọ́n sì kó gbogbo wọn, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”

16. Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Iná Ọlọrun wá láti ọ̀run, ó jó àwọn aguntan ati gbogbo darandaran patapata, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”

17. Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ tí iranṣẹ mìíràn fi tún dé, ó ní, “Àwọn ẹgbẹ́ ogun Kalidea mẹta kọlù wá, wọ́n kó gbogbo ràkúnmí wa lọ, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”

18. Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Bí àwọn ọmọ rẹ tí ń jẹ àsè ninu ilé ẹ̀gbọ́n wọn àgbà,

19. ìjì líle kan fẹ́ la àṣálẹ̀ kọjá, ó fẹ́ lu ilé náà, ó wó, ó sì pa gbogbo wọn, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”

20. Jobu bá dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn; ó fá orí rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì sin OLUWA.

21. Ó ní, “Ìhòòhò ni wọ́n bí mi, ìhòòhò ni n óo sì pada lọ. OLUWA níí fún ni ní nǹkan, OLUWA náà ní í sì í gbà á pada, ìyìn ni fún orúkọ OLUWA.”

22. Ninu gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀, kò sì dá Ọlọrun lẹ́bi.

Ka pipe ipin Jobu 1