Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 1:11-16 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ǹjẹ́, ìwọ mú gbogbo nǹkan wọnyi kúrò wò, o óo rí i pé yóo sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.”

12. OLUWA dá Satani lóhùn pé, “Ó dára, ohun gbogbo tí ó ní wà ní ìkáwọ́ rẹ. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan òun fúnra rẹ̀.” Satani bá kúrò níwájú OLUWA.

13. Ní ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Jobu ń jẹ àsè ninu ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkunrin, tí ó jẹ́ àgbà patapata,

14. iranṣẹ kan wá sọ́dọ̀ Jobu, ó ròyìn fún un pé, “Àwọn akọ mààlúù ń fi àjàgà wọn kọlẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹko nítòsí wọn;

15. àwọn ará Sabea rí wọn, wọ́n sì kó gbogbo wọn, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”

16. Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Iná Ọlọrun wá láti ọ̀run, ó jó àwọn aguntan ati gbogbo darandaran patapata, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”

Ka pipe ipin Jobu 1