Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 8:15-22 BIBELI MIMỌ (BM)

15. À ń retí alaafia,ṣugbọn ire kankan kò dé.Àkókò ìwòsàn ni à ń retí,ṣugbọn ìpayà ni a rí.

16. Ẹ gbọ́ bí ẹṣin wọn tí ń fọn imú, ní ilẹ̀ Dani;gbogbo ilẹ̀ ń mì tìtì nítorí ìró yíyan ẹṣin wọn.Wọ́n wá run ilẹ̀ náà,ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,ati ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.”

17. OLUWA ní, “Wò ó! N óo rán ejò sí ààrin yín:paramọ́lẹ̀ tí kò ní gbóògùn;wọn yóo sì bù yín jẹ.”

18. Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn,àárẹ̀ mú ọkàn mi.

19. Ẹ gbọ́ igbe àwọn eniyan mijákèjádò ilẹ̀ náà tí wọn ń bèèrè pé,“Ṣé OLUWA kò sí ní Sioni ni?Tabi ọba rẹ̀ kò sí ninu rẹ̀ ni?”OLUWA, ọba wọn dáhùn pé,“Kí ló dé tí wọn ń fi ère wọn mú mi bínú,pẹlu àwọn oriṣa ilẹ̀ àjèjì tí wọn ń bọ?”

20. Àwọn eniyan ní, “Ìkórè ti parí,àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn ti kọjá,sibẹ a kò rí ìgbàlà.”

21. Nítorí ọgbẹ́ àwọn eniyan mi ni ọkàn mi ṣe gbọgbẹ́.Mò ń ṣọ̀fọ̀, ìdààmú sì bá mi.

22. Ṣé kò sí ìwọ̀ra ní Gileadi ni?Àbí kò sí oníwòsàn níbẹ̀?Kí ló dé tí àìsàn àwọn eniyan mi kò sàn?

Ka pipe ipin Jeremaya 8