Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 6:18-30 BIBELI MIMỌ (BM)

18. OLUWA ní, “Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,kí ẹ̀yin eniyan sì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn.

19. Gbọ́! Ìwọ ilẹ̀;n óo fa ibi lé àwọn eniyan wọnyi lórí,wọn óo jèrè èso ìwà burúkú wọn;nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,wọ́n sì ti tàpá sí òfin mi.

20. Kí ni anfaani turari,tí wọn mú wá fún mi láti Ṣeba,tabi ti ọ̀pá turari olóòórùn dídùn tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè wá?N kò tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ sísun tí ẹ mú wá siwaju mi,bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ yín kò dùn mọ́ mi.

21. Nítorí náà, n óo gbé ohun ìdínà sọ́nà fún àwọn eniyan wọnyi,wọn óo sì fẹsẹ̀ kọ;ati baba, àtọmọ wọn,àtaládùúgbò, àtọ̀rẹ́,gbogbo wọn ni yóo parun.”

22. OLUWA ní,“Wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,orílẹ̀-èdè ńlá ń gbéra bọ̀ láti òpin ayé.

23. Wọ́n ń kó ọrun ati ọ̀kọ̀ bọ̀,ìkà ni wọ́n, wọn kò sì lójú àánú.Ìró wọn dàbí híhó omi òkun,bí wọ́n ti ń gun ẹṣin bọ̀.Wọ́n tò bí àwọn tí ń lọ sójú ogun,wọ́n dótì ọ́, ìwọ Jerusalẹmu!”

24. A gbúròó wọn, ọwọ́ wa rọ;ìdààmú dé bá wa,bí ìrora obinrin tí ó ń rọbí.

25. Ẹ má lọ sinu oko,ẹ má sì ṣe rìn lójú ọ̀nà náà,nítorí ọ̀tá mú idà lọ́wọ́,ìdágìrì sì wà káàkiri.

26. Ẹ̀yin eniyan mi,ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ máa yí ninu eérú;ẹ máa ṣọ̀fọ̀, bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo;kí ẹ sì máa sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóo bò yín.

27. Mo ti fi ọ́ ṣe ẹni tí yóo máa dán àwọn eniyan mi wò,o óo máa dán wọn wò bí ẹni dán irin wò,o óo gbìyànjú láti mọ ọ̀nà wọn,kí o lè yẹ ọ̀nà wọn wò, kí o sì mọ̀ ọ́n.

28. Ọlọ̀tẹ̀, aláìgbọràn ni gbogbo wọn,wọn á máa sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn.Wọ́n dàbí idẹ àdàlú mọ́ irin,àmúlùmálà ni gbogbo wọn.

29. Lóòótọ́ à ń fi ẹwìrì fẹ́ iná,òjé sì ń yọ́ lórí iná;ṣugbọn alágbẹ̀dẹ ń yọ́ irin lásán ni,kò mú ìbàjẹ́ ara rẹ̀ kúrò.

30. Ìdọ̀tí fadaka tí a kọ̀ tì ni wọ́n,nítorí pé OLUWA ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremaya 6