Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 45:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya wolii sọ fún Baruku ọmọ Neraya nìyí, ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya, jọba ní Juda. Baruku ń kọ ohun tí Jeremaya ń sọ sílẹ̀ bí Jeremaya tí ń sọ̀rọ̀.

2. Ó ní: “OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún ìwọ Baruku pé,

3. ò ń sọ pé, o gbé, nítorí pé OLUWA ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora rẹ; àárẹ̀ mú ọ nítorí ìkérora rẹ, o kò sì ní ìsinmi.

4. “Èmi ń wó ohun tí mo kọ́ lulẹ̀, mo sì ń tu ohun tí mo gbìn, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ gbogbo ilẹ̀ náà rí.

5. Ìwọ ń wá nǹkan ńlá fún ara tìrẹ? Má wá nǹkan ńlá fún ara rẹ. Wò ó, n óo mú kí ibi bá gbogbo eniyan, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; ṣugbọn n óo jẹ́ kí o máa sá àsálà ní gbogbo ibi tí o bá ń lọ.”

Ka pipe ipin Jeremaya 45