Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 43:9-13 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ó ní, “Gbé òkúta ńláńlá lọ́wọ́, kí o bò wọ́n mọ́lẹ̀, níbi pèpéle tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà ààfin Farao ní Tapanhesi, lójú àwọn ará Juda,

10. kí o sì wí fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo lọ mú Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ òun wá, yóo sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ka orí àwọn òkúta tí òun rì mọ́lẹ̀ yìí, Nebukadinesari yóo sì tẹ́ ìtẹ́ ọlá rẹ̀ sórí wọn.

11. Yóo wá kọlu ilẹ̀ Ijipti, yóo jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn tí yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn, yóo kó àwọn tí yóo lọ sí ìgbèkùn lọ sí ìgbèkùn, yóo sì fi idà pa àwọn tí yóo kú ikú idà.

12. Yóo dáná sun àwọn ilé àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti; yóo jó wọn níná; yóo sì kó àwọn ará ìlú lọ sí ìgbèkùn; yóo fọ ilẹ̀ Ijipti mọ́ bí darandaran tíí ṣa eégbọn kúrò lára aṣọ rẹ̀, yóo sì jáde kúrò níbẹ̀ ní alaafia.

13. Yóo fọ́ àwọn òpó ilé oriṣa Heliopolisi tí ó wà ní ilẹ̀ Ijipti, yóo sì dáná sun àwọn ilé àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti.”

Ka pipe ipin Jeremaya 43