Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 42:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn olórí ogun ati Johanani, ọmọ Karea ati Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati gbogbo àwọn ará Juda, lọ́mọdé ati lágbà, tọ wolii Jeremaya lọ.

2. Wọ́n wí fún un pé, “Nǹkan kan ni a fẹ́ bẹ̀ ọ́ fún, a sì fẹ́ kí o ṣe é fún wa: jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún àwa ati gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, nítorí pé a ti pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn díẹ̀ ninu wa ni ó kù, bí ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí i.

3. A fẹ́ kí OLUWA Ọlọrun rẹ lè fi ọ̀nà tí a óo gbà hàn wá, kí ó sọ ohun tí a óo ṣe fún wa.”

4. Wolii Jeremaya bá dá wọn lóhùn pé, “Mo gbọ́, n óo gbadura sí OLUWA Ọlọrun yín bí ẹ ti wí; gbogbo ìdáhùn tí OLUWA bá fún mi ni n óo sọ fun yín, n kò ní fi nǹkankan pamọ́.”

5. Wọ́n wí fún Jeremaya pé, “Kí OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ ati òdodo bí a kò bá ṣe gbogbo nǹkan tí OLUWA Ọlọrun bá ní kí o sọ fún wa.

6. Ìbáà jẹ́ rere ni OLUWA Ọlọrun wa tí a rán ọ sí sọ, kì báà jẹ́ burúkú, a óo gbọ́ràn sí i lẹ́nu; kí ó lè dára fún wa; nítorí pé ti OLUWA Ọlọrun wa ni a óo gbọ́.”

7. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwaa, OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀.

8. Jeremaya bá pe Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki.

9. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ẹ ní kí n gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ siwaju rẹ̀ ní,

10. ‘Bí ẹ bá dúró ní ilẹ̀ yìí, n óo kọ yín bí ilé, n kò sì ní wo yín lulẹ̀. N óo gbìn yín bí igi, n kò sì ní fà yín tu, nítorí mo ti yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo ṣe sí yín.

Ka pipe ipin Jeremaya 42