Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 41:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Nígbà tí Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gbọ́ gbogbo iṣẹ́ ibi tí Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ṣe,

12. wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn lọ gbógun ti Iṣimaeli, wọ́n bá a létí odò ńlá tí ó wà ní Gibeoni.

13. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Iṣimaeli rí Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, inú wọn dùn.

14. Ni gbogbo àwọn tí Iṣimaeli kó lẹ́rú ní Misipa bá yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n lọ bá Johanani ọmọ Karea.

15. Ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, pẹlu àwọn mẹjọ sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

16. Lẹ́yìn náà Johanani ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, kó gbogbo àwọn tí Iṣimaeli ọmọ Netanaya kó lẹ́rú ní Misipa, lẹ́yìn tí ó pa Gedalaya ọmọ Ahikamu tán, ó bá kó ati àwọn ọmọ ogun, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde, ati àwọn ìwẹ̀fà, pada wá láti Gibeoni.

17. Wọ́n lọ ń gbé Geruti Kimhamu, tí ó wà lẹ́bàá Bẹtilẹhẹmu. Wọ́n pinnu láti kó lọ sí ilẹ̀ Ijipti nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea ń bà wọ́n;

18. nítorí pé Iṣimaeli ọmọ Netanaya ti pa Gedalaya, ọmọ Ahikamu, tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà.

Ka pipe ipin Jeremaya 41