Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 4:19-28 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Oró ò! Oró ò!Mò ń jẹ̀rora!Àyà mi ò!Àyà mi ń lù kìkìkì,n kò sì lè dákẹ́;nítorí mo gbọ́ ìró fèrè ogun, ati ariwo ogun.

20. Àjálù ń ṣubú lu àjálù,gbogbo ilẹ̀ ti parun.Lójijì àgọ́ mi wó lulẹ̀,aṣọ títa mi sì fàya ní ìṣẹ́jú kan.

21. Yóo ti pẹ́ tó tí n óo máa wo àsíá ogun,tí n óo sì máa gbọ́ fèrè ogun?

22. OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn eniyan mi gọ̀,wọn kò mọ̀ mí.Òmùgọ̀ ọmọ ni wọ́n;wọn kò ní òye.Ọgbọ́n àtiṣe ibi kún inú wọn:ṣugbọn wọn kò mọ rere ṣe.”

23. Mo bojú wo ilé ayé, ilé ayé ṣófo,ó rí júujùu;mo ṣíjú wo ojú ọ̀run,kò sí ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.

24. Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n ń mì tìtì,gbogbo òkè kéékèèké ń sún lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún.

25. Mo wò yíká, n kò rí ẹnìkan,gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ti fò sálọ.

26. Mo wò yíká, mo rí i pé gbogbo ilẹ̀ ọlọ́ràá ti di aṣálẹ̀,gbogbo ìlú sì ti di òkítì àlàpà níwájú OLUWA,nítorí ibinu ńlá rẹ̀.

27. Nítorí OLUWA ti sọ pé,gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro;sibẹ òpin kò ní tíì dé.

28. Nítorí èyí, ilẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀,ojú ọ̀run yóo sì ṣókùnkùn.Nítorí pé ó ti sọ bẹ́ẹ̀,ó ti rò ó dáradára, kò tíì jáwọ́ ninu rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní yipada.

Ka pipe ipin Jeremaya 4