Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 4:17-30 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Wọ́n yí i ká bí àwọn tí ó ń ṣọ́ oko,nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA.OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

18. Ìrìn ẹsẹ̀ rẹ ati ìwà rẹni ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá ọ.Ìjìyà rẹ nìyí, ó sì korò;ó ti dé oókan àyà rẹ.

19. Oró ò! Oró ò!Mò ń jẹ̀rora!Àyà mi ò!Àyà mi ń lù kìkìkì,n kò sì lè dákẹ́;nítorí mo gbọ́ ìró fèrè ogun, ati ariwo ogun.

20. Àjálù ń ṣubú lu àjálù,gbogbo ilẹ̀ ti parun.Lójijì àgọ́ mi wó lulẹ̀,aṣọ títa mi sì fàya ní ìṣẹ́jú kan.

21. Yóo ti pẹ́ tó tí n óo máa wo àsíá ogun,tí n óo sì máa gbọ́ fèrè ogun?

22. OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn eniyan mi gọ̀,wọn kò mọ̀ mí.Òmùgọ̀ ọmọ ni wọ́n;wọn kò ní òye.Ọgbọ́n àtiṣe ibi kún inú wọn:ṣugbọn wọn kò mọ rere ṣe.”

23. Mo bojú wo ilé ayé, ilé ayé ṣófo,ó rí júujùu;mo ṣíjú wo ojú ọ̀run,kò sí ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.

24. Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n ń mì tìtì,gbogbo òkè kéékèèké ń sún lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún.

25. Mo wò yíká, n kò rí ẹnìkan,gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ti fò sálọ.

26. Mo wò yíká, mo rí i pé gbogbo ilẹ̀ ọlọ́ràá ti di aṣálẹ̀,gbogbo ìlú sì ti di òkítì àlàpà níwájú OLUWA,nítorí ibinu ńlá rẹ̀.

27. Nítorí OLUWA ti sọ pé,gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro;sibẹ òpin kò ní tíì dé.

28. Nítorí èyí, ilẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀,ojú ọ̀run yóo sì ṣókùnkùn.Nítorí pé ó ti sọ bẹ́ẹ̀,ó ti rò ó dáradára, kò tíì jáwọ́ ninu rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní yipada.

29. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin ati ti àwọn tafàtafà,gbogbo ìlú sá jáde fún ààbò.Wọ́n sá wọ inú igbó lọ,wọ́n gun orí òkè lọ sinu pàlàpálá òkúta;gbogbo ìlú sì di ahoro.

30. Ìwọ tí o ti di ahoro,kí ni èrò rẹ tí o fi wọ aṣọ elése àlùkò?Tí o wa nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà sára?Tí o tọ́ ojú?Tí o tọ́ ètè?Asán ni gbogbo ọ̀ṣọ́ tí o ṣe,àwọn olólùfẹ́ rẹ kò kà ọ́ sí,ọ̀nà ati gba ẹ̀mí rẹ ni wọ́n ń wá.

Ka pipe ipin Jeremaya 4