Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 39:9-18 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá kó àwọn eniyan tí wọn ṣẹ́kù ní Jerusalẹmu ní ìgbèkùn, lọ sí Babiloni pẹlu àwọn tí wọn kọ́ sá lọ bá a tẹ́lẹ̀.

10. Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ó sì fún wọn ní ọgbà àjàrà ati oko.

11. Nebukadinesari ọba Babiloni pàṣẹ fún Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ pé

12. kí wọn mú Jeremaya, kí wọn tọ́jú rẹ̀ dáradára, kí wọn má pa á lára, ṣugbọn kí wọn ṣe ohunkohun tí ó bá ń fẹ́ fún un.

13. Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ati Nebuṣasibani, ìjòyè pataki kan, ati Negali Sareseri olóyè pataki mìíràn ati gbogbo àwọn olóyè jàǹkànjàǹkàn ninu àwọn ìjòyè ọba Babiloni,

14. wọ́n ranṣẹ lọ mú Jeremaya jáde kúrò ní ìgbèkùn. Wọ́n bá fà á lé Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani lọ́wọ́, pé kí ó mú un lọ sí ilé rẹ̀. Ó bá ń gbé ààrin àwọn eniyan náà.

15. OLUWA sọ fún Jeremaya nígbà tí ó wà ní àtìmọ́lé ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba, pé,

16. kí ó lọ sọ fún Ebedimeleki ará Etiopia pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Wò ó, n óo mú ìpinnu ibi tí mo ṣe lórí ìlú yìí ṣẹ, lójú rẹ ni yóo sì ṣẹ.

17. N óo gbà ọ́ sílẹ̀ ní ọjọ́ náà, wọn kò ní fà ọ́ lé àwọn tí ò ń bẹ̀rù lọ́wọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

18. Nítorí pé, dájúdájú n óo gbà ọ́ sílẹ̀, o ò ní kú ikú idà, ṣugbọn o óo sá àsálà, nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé mi.”

Ka pipe ipin Jeremaya 39