1. Ní ọdún kẹrin ìjọba Jehoiakimu ọmọ Josaya ọba Juda, OLUWA sọ fún Jeremaya pé,
2. “Mú ìwé kíká kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ nípa Israẹli ati Juda ati gbogbo orílẹ̀-èdè sinu rẹ̀. Gbogbo ohun tí mo sọ láti ọjọ́ tí mo ti ń bá ọ sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Josaya títí di òní, ni kí o kọ.
3. Bóyá bí àwọn ará Juda bá gbọ́ nípa ibi tí mò ń gbèrò láti ṣe sí wọn, olukuluku lè yipada kúrò ninu ọ̀nà ibi rẹ̀, kí n lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára wọn jì wọ́n.”
4. Jeremaya bá pe Baruku ọmọ Neraya, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá a sọ fún un, Baruku bá kọ wọ́n sinu ìwé kíká kan.