Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 34:18-22 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Àwọn ọkunrin tí wọn bá rú òfin mi, tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà majẹmu tí wọn dá níwájú mi, n óo bẹ́ wọn bíi ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí wọn bẹ́ sí meji, tí wọ́n sì gba ààrin rẹ̀ kọjá.

19. Bí àwọn ìjòyè Juda ati àwọn ìjòyè Jerusalẹmu, àwọn ìwẹ̀fà, àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ṣe bẹ́ ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù sí meji, tí wọn sì gba ààrin rẹ̀ kọjá láti bá mi dá majẹmu, ni n óo ṣe bẹ́ àwọn náà.

20. N óo fà wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn; òkú wọn yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.

21. N óo fi Sedekaya, ọba Juda ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn. Wọn óo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni tí ó ti ṣígun kúrò lọ́dọ̀ wọn.

22. Ẹ wò ó, n óo pàṣẹ, n óo sì kó wọn pada sí ìlú yìí, wọn yóo gbógun tì í, wọn yóo gbà á; wọn yóo sì dáná sun ún. N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro, kò ní sí eniyan tí yóo máa gbé inú wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremaya 34