Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 34:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá Jeremaya sọ nìyí, nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati gbogbo ìjọba ayé tí wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀, ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbógun ti Jerusalẹmu ati gbogbo àwọn ìlú Juda.

2. OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, kí n lọ sọ fún Sedekaya, ọba Juda pé òun OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ìlú yìí lé ọba Babiloni lọ́wọ́; yóo sì dáná sun ún.

3. Sedekaya, o kò ní sá àsálà, ṣugbọn wọn óo mú ọ, wọn óo fà ọ́ lé Nebukadinesari lọ́wọ́, ẹ óo rí ara yín lojukooju, ẹ óo bá ara yín sọ̀rọ̀, o óo sì lọ sí Babiloni.

4. Sibẹsibẹ, ìwọ Sedekaya, ọba Juda OLUWA ní wọn kò ní fi idà pa ọ́.

5. O óo fi ọwọ́ rọrí kú ni. Bí wọn ti sun turari níbi òkú àwọn baba rẹ, ati níbi òkú àwọn ọba tí wọ́n ti kú ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo sun turari níbi òkú ìwọ náà. Wọn yóo dárò rẹ, wọn yóo máa wí pé, ‘Ó ṣe, oluwa mi,’ nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA ṣe ìlérí; èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremaya 34