Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 33:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹẹkeji, nígbà tí ó ṣì wà ní ẹ̀wọ̀n, ní àgbàlá àwọn tí ń ṣọ́ ààfin.

2. OLUWA tí ó dá ayé, tí ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA, ni ó sọ pé:

3. “Ẹ ké pè mí, n óo sì da yín lóhùn; n óo sọ nǹkan ìjìnlẹ̀ ati ìyanu ńlá, tí ẹ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ fun yín.”

4. OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn ilé tí wọ́n wà ní ìlú yìí, ati ilé ọba Juda, àwọn tí wọn dótì wá, tí wọn ń gbógun tì wá yóo wó wọn lulẹ̀

5. Ó ní, “Àwọn ará Kalidea ń gbógun bọ̀, wọn yóo da òkú àwọn eniyan tí n óo fi ibinu ati ìrúnú pa kún àwọn ilé tí ó wà ní ìlú yìí, nítorí mo ti fi ara pamọ́ fún ìlú yìí nítorí gbogbo ìwà burúkú wọn.

6. N óo mú ìlera ati ìwòsàn wá bá wọn; n óo wò wọ́n sàn, n óo sì fún wọn ní ọpọlọpọ ibukun ati ìfọ̀kànbalẹ̀.

7. N óo dá ire Juda ati ti Israẹli pada, n óo sì tún wọn kọ́, wọn yóo dàbí wọ́n ti rí lákọ̀ọ́kọ́.

8. N óo wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí mi, n óo dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati oríkunkun tí wọ́n ṣe sí mi jì wọ́n.

9. Orúkọ ìlú yìí yóo sì jẹ́ orúkọ ayọ̀ fún mi, yóo jẹ́ ohun ìyìn ati ògo níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé tí yóo gbọ́ nípa nǹkan rere tí n óo ṣe fún wọn; ẹ̀rù yóo bà wọ́n, wọn yóo sì wárìrì, nítorí gbogbo nǹkan rere tí n óo máa ṣe fún ìlú náà.”

Ka pipe ipin Jeremaya 33