Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 31:10-21 BIBELI MIMỌ (BM)

10. OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ èmi OLUWA, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,kí ẹ sì kéde rẹ̀ ní èbúté lókèèrè réré;ẹ sọ pé, ‘Ẹni tí ó fọ́n Israẹli ká ni yóo kó wọn jọ,yóo sì máa tọ́jú wọn, bí olùṣọ́-aguntan tíí tọ́jú agbo aguntan rẹ̀.’

11. Nítorí OLUWA yóo ra ilé Jakọbu pada,yóo rà wọ́n pada lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára jù wọ́n lọ.

12. Wọn yóo wá kọrin lórí òkè Sioni,wọn óo sì yọ̀ lórí nǹkan ọ̀pọ̀ oore tí OLUWA yóo ṣe fún wọn:Wọ́n óo yọ̀ nítorí oore ọkà ati waini ati òróró,ati aguntan ati ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù;ayé wọn óo dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, wọn kò ní dààmú mọ́.

13. Àwọn ọdọmọbinrin óo máa jó ijó ayọ̀ nígbà náà,àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn àgbààgbà, yóo sì máa ṣe àríyá.N óo sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,n óo tù wọ́n ninu, n óo sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́ wọn.

14. N óo fún àwọn alufaa ní ọpọlọpọ oúnjẹ,n óo sì fi oore mi tẹ́ àwọn eniyan mi lọ́rùn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

15. OLUWA ní,“A gbọ́ ohùn kan ní Rama,ariwo ẹkún ẹ̀dùn ati arò ni.Rakẹli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀,wọ́n ṣìpẹ̀ fún un títí, kò gbà,nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́.

16. Má sọkún mọ́, nu ojú rẹ nù,nítorí o óo jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.Àwọn ọmọ rẹ yóo pada wá láti ilẹ̀ ọ̀tá wọn.

17. Ìrètí ń bẹ fún ọ lẹ́yìn ọ̀la,àwọn ọmọ rẹ yóo pada sí orílẹ̀-èdè wọn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

18. “Mo gbọ́ bí Efuraimu tí ń kẹ́dùn,ó ní: ‘O ti bá mi wí, ìbáwí sì dùn mí,bí ọmọ mààlúù tí a kò kọ́.Mú mi pada, kí n lè pada sí ààyè mi,nítorí pé ìwọ ni OLUWA, Ọlọrun mi.

19. Nítorí pé lẹ́yìn tí mo ṣáko lọ, mo ronupiwada;lẹ́yìn tí o kọ́ mi lọ́gbọ́n, ń ṣe ni mo káwọ́ lérí.Ojú tì mí, ìdààmú sì bá mi,nítorí ìtìjú ohun tí mo ṣe nígbà èwe mi dé bá mi.’

20. “Ṣé ọmọ mi ọ̀wọ́n ni Efuraimu ni?Ṣé ọmọ mi àtàtà ni?Nítorí bí mo tí ń sọ̀rọ̀ ibinu sí i tó, sibẹ mò ń ranti rẹ̀,nítorí náà ọkàn rẹ̀ ń fà mí;dájúdájú n óo ṣàánú rẹ̀.

21. Ẹ ri òpó mọ́lẹ̀ lọ fún ara yín,ẹ sàmì sí àwọn ojú ọ̀nà.Ẹ wo òpópónà dáradára, ẹ fiyèsí ọ̀nà tí ẹ gbà lọ.Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ Israẹli,ẹ pada sí àwọn ìlú yín wọnyi.

Ka pipe ipin Jeremaya 31