Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 29:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jeremaya wolii kọ ìwé kan ranṣẹ láti Jerusalẹmu, ó kọ ọ́ sí àwọn àgbààgbà láàrin àwọn tí a kó ní ìgbèkùn; ati sí àwọn alufaa ati àwọn wolii, ati gbogbo àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, láti Jerusalẹmu.

2. Ṣáájú àkókò yìí, ọba Jehoiakini ati ìyá ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, pẹlu àwọn ìwẹ̀fà ati àwọn ìjòyè Juda ati ti Jerusalẹmu, ati àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati àwọn oníṣẹ́-ọnà.

3. Ó fi ìwé náà rán Elasa, ọmọ Ṣafani ati Gemaraya, ọmọ Hilikaya: àwọn tí Sedekaya, ọba Juda, rán lọ sọ́dọ̀ Nebukadinesari, ọba Babiloni.

4. Ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí n sọ fún gbogbo àwọn tí a ti kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni pé,

5. ‘Ẹ máa kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé inú wọn, ẹ máa dá oko kí ẹ sì máa jẹ èso wọn.

6. Ẹ máa gbé iyawo kí ẹ bímọ lọkunrin ati lobinrin. Ẹ máa fẹ́ iyawo fún àwọn ọmọ yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọ yín fún ọkọ, kí wọn lè máa bímọ lọkunrin ati lobinrin. Ẹ máa pọ̀ sí i, ẹ má sì dínkù.

7. Ẹ máa wá alaafia ìlú tí mo ko yín lọ, ẹ máa gbadura sí OLUWA fún un, nítorí pé ninu alaafia rẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ti ní alaafia.

8. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé kí ẹ má jẹ́ kí àwọn wolii ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ láàrin yín tàn yín jẹ, kí ẹ má sì fetí sí àlá tí wọn ń lá;

9. nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́.’

Ka pipe ipin Jeremaya 29