Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 28:10-17 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Hananaya wolii bá bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, ó sì ṣẹ́ ẹ.

11. Hananaya bá sọ níṣojú gbogbo eniyan pé OLUWA ní bẹ́ẹ̀ ni òun óo ṣẹ́ àjàgà Nebukadinesari ọba Babiloni kúrò lọ́rùn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè kí ọdún meji tó pé. Wolii Jeremaya bá bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

12. Lẹ́yìn tí Hananaya wolii bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, tí ó sì ṣẹ́ ẹ, OLUWA sọ fún Jeremaya pé,

13. “Lọ sọ fún Hananaya pé OLUWA ní àjàgà igi ni ó ṣẹ́, ṣugbọn àjàgà irin ni òun óo fi rọ́pò rẹ̀.

14. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ti fi àjàgà irin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè wọnyi kí wọn lè di ẹrú Nebukadinesari ọba Babiloni, kí wọn sì máa sìn ín, nítorí òun ti fi àwọn ẹranko inú igbó pàápàá fún un.”

15. Jeremaya wolii bá sọ fún Hananaya pé, “Tẹ́tí sílẹ̀, Hananaya, OLUWA kò rán ọ níṣẹ́, o sì ń jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gbẹ́kẹ̀lé irọ́.

16. Nítorí náà, OLUWA ní: òun óo mú ọ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ní ọdún yìí gan-an ni o óo sì kú, nítorí pé o ti sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.”

17. Ní ọdún náà gan-an ní oṣù keje, ni Hananaya wolii kú.

Ka pipe ipin Jeremaya 28