Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 22:22-30 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Afẹ́fẹ́ yóo fẹ́ gbogbo àwọn olórí yín lọ,àwọn olólùfẹ́ yín yóo lọ sí ìgbèkùn.Ojú yóo wá tì yín,ẹ óo sì di ẹni ẹ̀tẹ́,nítorí gbogbo ibi tí ẹ̀ ń ṣe.

23. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Lẹbanoni,tí ẹ kọ́ ilé yín sí ààrin igi kedari.Ẹ óo kérora nígbà tí ara bá ń ni yín,tí ara ń ni yín bíi ti obinrin tí ń rọbí ọmọ!

24. OLUWA sọ fún Jehoiakini ọba, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, pé, “Mo fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ ni òrùka èdìdì ọwọ́ ọ̀tún mi,

25. n óo bọ́ ọ kúrò, n óo sì fi ọ́ lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ati àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ, tí ẹ̀rù wọn sì ń bà ọ́.

26. N óo wọ́ ìwọ ati ìyá tí ó bí ọ jù sí ilẹ̀ àjèjì, tí kì í ṣe ibi tí wọ́n bí ọ sí, ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí.

27. Ṣugbọn ilẹ̀ tí ọkàn yín fẹ́ pada sí, ẹ kò ní pada sibẹ mọ́.”

28. Ṣé àfọ́kù ìkòkò tí ẹnikẹ́ni kò kà kún ni Jehoiakini?Àbí o ti di ohun èlò àlòpatì?Kí ló dé tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀fi di ẹni tí a kó lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀ rí?

29. Ilẹ̀! Ilẹ̀!Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ!

30. Ó ní, “Ẹ kọ orúkọ ọkunrin yìí sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ,ẹni tí kò ní ṣe rere kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀;nítorí pé kò sí ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀tí yóo rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi,Ìdílé rẹ̀ kò sì ní jọba mọ ní Juda.”

Ka pipe ipin Jeremaya 22