Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 22:17-23 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ṣugbọn níbi èrè aiṣododo nìkan ni ojú ati ọkàn yín ń wà,níbi kí ẹ máa pa aláìṣẹ̀, kí ẹ máa ni eniyan lára,kí ẹ sì máa hùwà ìkà.

18. Nítorí náà, OLUWA sọ nípa Jehoiakimu, ọba Juda, ọmọ Josaya pé,wọn kò ní dárò rẹ̀, pé,“Ó ṣe, arakunrin mi!”Tabi pé, “Ó ṣe, arabinrin mi!”Wọn kò ní ké pé,“Ó ṣe, oluwa mi!” Tabi pé, “Ó ṣe! Áà! Kabiyesi!”

19. Bí ẹni ń ṣe òkú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni wọ́n óo ṣe òkú rẹ̀;ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu ni wọn yóo wọ́ ọ jù sí.Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu,

20. ẹ gun orí òkè Lẹbanoni lọ, kí ẹ kígbe.Ẹ dúró lórí òkè Baṣani, kí ẹ pariwo gidigidi,ẹ kígbe láti orí òkè Abarimu,nítorí pé a ti pa gbogbo àwọn alájọṣe yín run.

21. OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ nígbà tí nǹkan ń dára fun yín,ṣugbọn ẹ sọ pé ẹ kò ní gbọ́.Bẹ́ẹ̀ ni ẹ tí ń ṣe láti kékeré yín,ẹ kì í gbọ́rọ̀ sí OLUWA lẹ́nu.

22. Afẹ́fẹ́ yóo fẹ́ gbogbo àwọn olórí yín lọ,àwọn olólùfẹ́ yín yóo lọ sí ìgbèkùn.Ojú yóo wá tì yín,ẹ óo sì di ẹni ẹ̀tẹ́,nítorí gbogbo ibi tí ẹ̀ ń ṣe.

23. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Lẹbanoni,tí ẹ kọ́ ilé yín sí ààrin igi kedari.Ẹ óo kérora nígbà tí ara bá ń ni yín,tí ara ń ni yín bíi ti obinrin tí ń rọbí ọmọ!

Ka pipe ipin Jeremaya 22