Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 2:5-10 BIBELI MIMỌ (BM)

5. OLUWA ní: “Nǹkan burúkú wo ni àwọn baba ńlá yín ní mo fi ṣe àwọn, tí wọ́n jìnnà sí mi; tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ síí bọ oriṣa lásánlàsàn, tí àwọn pàápàá sì fi di eniyan lásán?

6. Wọn kò bèèrè pé, Níbo ni OLUWA wà,ẹni tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti,tí ó sìn wá la aṣálẹ̀ já,ilẹ̀ aṣálẹ̀ tí ó kún fún ọ̀gbun,ilẹ̀ ọ̀dá ati òkùnkùn biribiri,ilẹ̀ tí eniyan kìí là kọjá,tí ẹnikẹ́ni kì í gbé?

7. Mo mu yín wá sí ilẹ̀ tí ó lọ́ràá,pé kí ẹ máa gbádùn èso rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára tí wọ́n wà ninu rẹ̀,ṣugbọn nígbà tí ẹ dé inú rẹ̀, ẹ sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́,ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.

8. Àwọn alufaa kò bèèrè pé, ‘OLUWA dà?’Àwọn tí wọn ń ṣe àmójútó òfin kò mọ̀ mí,àwọn olórí ń dìtẹ̀ sí mi,àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ oriṣa Baali,wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa lásánlàsàn.

9. “Nítorí náà, mò ń ba yín rojọ́,n óo sì tún bá arọmọdọmọ yín rojọ́ pẹlu.”OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

10. Ó ní, “Ẹ kọjá sí èbúté àwọn ará Kipru kí ẹ wò yíká,tabi kí ẹ ranṣẹ sí Kedari kí ẹ sì ṣe ìwádìí fínnífínní,bóyá irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ rí.

Ka pipe ipin Jeremaya 2