Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 18:3-16 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Mo bá lọ sí ilé amọ̀kòkò. Mo bá a tí ó ń mọ ìkòkò kan lórí òkúta tí wọn fi ń mọ ìkòkò.

4. Ìkòkò tí ó ń fi amọ̀ mọ bàjẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó bá fi amọ̀ náà mọ ìkòkò mìíràn, tí ó wù ú.

5. OLUWA bá sọ fún mi pé,

6. “Ẹ̀yin ilé Israẹli, ṣé n kò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ìkòkò tí ó mọ ni? Bí amọ̀ ti rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.

7. Bí mo bá sọ pé n óo fa orílẹ̀-èdè kan, tabi ìjọba kan tu, n óo wó o lulẹ̀, n óo sì pa á run,

8. bí orílẹ̀-èdè ọ̀hún bá yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀, n óo dá ibi tí mo ti fẹ́ ṣe sí i tẹ́lẹ̀ dúró.

9. Bí mo bá sọ pé n óo gbé orílẹ̀-èdè kan dìde, n óo sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀;

10. bí ó bá ṣe nǹkan burúkú lójú mi, tí kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, n óo dá nǹkan rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún un dúró.

11. Nítorí náà, sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, èmi OLUWA ní, mò ń pète ibi kan si yín, mo sì ń pinnu rẹ̀ lọ́wọ́ báyìí, kí olukuluku yín yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe; kí ẹ sì tún ìwà ati ìṣe yín ṣe.

12. Ṣugbọn wọ́n ń wí pé, ‘Rárá o, OLUWA kàn ń sọ tirẹ̀ ni, tinú wa ni a óo ṣe, olukuluku yóo máa lo agídí ọkàn rẹ̀.’ ”

13. Nítorí náà OLUWA ní,“Ẹ bèèrè láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè,bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ irú rẹ̀ rí.Israẹli ti ṣe ohun tó burú gan-an.

14. Ṣé yìnyín òkè Lẹbanoni a máa dà ní pàlàpálá Sirioni?Àbí omi tútù tí máa ń ṣàn láti inú òkè rẹ̀ a máa gbẹ?

15. Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti gbàgbé mi,wọ́n ń sun turari sí oriṣa èké.Wọ́n ti kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà àtijọ́ tí wọn ń tọ̀,wọ́n ti yà sí ọ̀nà ojúgbó tí kì í ṣe ojú ọ̀nà tààrà.

16. Wọ́n sọ ilẹ̀ wọn di ohun ẹ̀rù ati ohun àrípòṣé títí lae.Gbogbo àwọn tí wọn bá gba ibẹ̀ kọjá ni ẹ̀rù yóo máa bà,tí wọn yóo sì máa mi orí.

Ka pipe ipin Jeremaya 18