Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 17:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní, “Gègé irin ni a fi kọ ẹ̀ṣẹ̀ Juda sílẹ̀ gègé òkúta dayamọndi ni a sì fi kọ ọ́ sí ọkàn yín, ati sí ara ìwo ara pẹpẹ wọn,

2. níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá ń ranti àwọn pẹpẹ yín, ati àwọn oriṣa Aṣera yín, tí ẹ rì mọ́ ẹ̀gbẹ́ gbogbo igi tútù, ati lórí àwọn òkè gíga;

3. ati lórí àwọn òkè ninu pápá. N óo sọ gbogbo ọrọ̀ yín ati gbogbo ohun ìṣúra yín di ìkógun fún àwọn ọ̀tá yín; n óo fi gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín.

4. Ìwà yín yóo mú kí ilẹ̀ tí mo fun yín bọ́ lọ́wọ́ yín; n óo sí sọ yín di ẹrú àwọn ọ̀tá yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò mọ̀rí. Ẹ ti mú kí ibinu mi máa jó bí iná, kò sì ní kú títí lae.”

5. OLUWA ní,“Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan,tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀;tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA.

6. Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀,nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i.Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà,ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé.

7. “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,tí ó fi OLUWA ṣe àgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

8. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí ipa odò,tí ó ta gbòǹgbò kan ẹ̀bá odò.Ẹ̀rù kò ní bà á nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé,nítorí pé ewé rẹ̀ yóo máa tutù minimini.Kò ní páyà lákòókò ọ̀gbẹlẹ̀,nígbà gbogbo ni yóo sì máa so.

Ka pipe ipin Jeremaya 17