Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 14:8-12 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ìwọ ìrètí Israẹli,olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro.Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà?Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú?

9. Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá;bí alágbára tí kò lè gbani là?Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA,a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá,má fi wá sílẹ̀.’ ”

10. OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé,“Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri,wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn;nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA,nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn,yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

11. OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia.

12. Wọn ìbáà gbààwẹ̀, n kò ní gbọ́ igbe wọn. Wọn ìbáà rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, n kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Idà, ati ebi, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ni n óo fi pa wọ́n run.”

Ka pipe ipin Jeremaya 14