Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 10:8-15 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Aláìmọ̀kan ati òmùgọ̀ ni gbogbo wọn,ère kò lè kọ́ eniyan lọ́gbọ́n,nítorí igi lásán ni.

9. Wọ́n kó fadaka pẹlẹbẹ wá láti ìlú Taṣiṣi,ati wúrà láti ìlú Ufasi.Iṣẹ́ ọwọ́ agbẹ́gilére ni wọ́n,ati ti àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà.Aṣọ wọn jẹ́ aláwọ̀ pupaati ti elése àlùkò,iṣẹ́ ọwọ́ àwọn oníṣọ̀nà ni gbogbo wọn.

10. Ṣugbọn OLUWA ni Ọlọrun tòótọ́,òun ni Ọlọrun alààyè, Ọba ayérayé.Tí inú rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ síí ru ayé á mì tìtì,àwọn orílẹ̀-èdè kò lè farada ibinu rẹ̀.

11. Wí fún wọn pé àwọn ọlọrun tí kì í ṣe àwọn ni wọ́n dá ọ̀run ati ayé yóo parun láyé ati lábẹ́ ọ̀run.

12. Òun ni ó fi agbára rẹ̀ dá ayé,tí ó fi ọgbọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀,tí ó sì fi òye rẹ̀ ta ojú ọ̀run bí aṣọ.

13. Bí ó bá fọhùn, omi á máa rọ́kẹ̀kẹ̀ lójú ọ̀run,ó mú kí ìkùukùu gbéra láti òpin ayé,òun ni ó dá mànàmáná fún òjò,tí ó sì mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.

14. Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan jẹ́, wọn kò sì ní ìmọ̀;gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ni àwọn oriṣa wọn dójútì,nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn ère wọn;kò sí èémí ninu wọn.

15. Asán ni wọ́n, ohun ìṣìnà sì ni wọ́n;ní àkókò ìjẹníyà wọn, wọn yóo parun ni.

Ka pipe ipin Jeremaya 10