Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 10:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLUWA ń ba yín sọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli:

2. OLUWA ní,“Ẹ má kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ẹ má sì páyà nítorí àwọn àmì ojú ọ̀run,bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tilẹ̀ ń páyà nítorí wọn,

3. nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn àṣà wọn.Wọn á gé igi ninu igbó,agbẹ́gilére á fi àáké gbẹ́ ẹ.

4. Wọn á fi fadaka ati wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,wọn á sì fi ìṣó kàn án mọ́lẹ̀,kí ó má baà wó lulẹ̀.

5. Ère wọn dàbí aṣọ́komásùn ninu oko ẹ̀gúsí,wọn kò lè sọ̀rọ̀,gbígbé ni wọ́n máa ń gbé wọnnítorí pé wọn kò lè dá rìn.Ẹ má bẹ̀rù wọnnítorí pé wọn kò lè ṣe ẹnikẹ́ni ní ibi kankan,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì lè ṣe rere.”

6. OLUWA, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, o tóbi lọ́ba,agbára orúkọ rẹ sì pọ̀.

7. Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè?Nítorí ẹ̀tọ́ rẹ ni;kò sì sí ẹni tí ó gbọ́n tó ọláàrin àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè,ati ni gbogbo ìjọba wọn.

Ka pipe ipin Jeremaya 10