Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 8:9-20 BIBELI MIMỌ (BM)

9. ṣugbọn àdàbà náà kò rí ibi tí ó lè bà sí nítorí pé omi bo gbogbo ilẹ̀, ó bá fò pada tọ Noa lọ ninu ọkọ̀. Noa na ọwọ́ jáde láti inú ọkọ̀, ó sì mú un wọlé.

10. Ó dúró fún ọjọ́ meje kí ó tó tún rán àdàbà náà jáde.

11. Àdàbà náà fò pada ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà pẹlu ewé olifi tútù ní ẹnu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Noa ṣe mọ̀ pé omi ti fà lórí ilẹ̀.

12. Ó tún dúró fún ọjọ́ meje sí i, lẹ́yìn náà, ó tún rán àdàbà náà jáde, ṣugbọn àdàbà náà kò pada sọ́dọ̀ Noa mọ́.

13. Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni ọdún tí Noa di ẹni ọdún mọkanlelẹgbẹta (601), omi gbẹ tán lórí ilẹ̀. Noa ṣí òrùlé ọkọ̀, ó yọjú wo ìta, ó sì rí i pé ilẹ̀ ti gbẹ.

14. Ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù keji ni ilẹ̀ gbẹ tán patapata.

15. Ọlọrun sọ fún Noa pé,

16. “Jáde kúrò ninu ọkọ̀, ìwọ ati aya rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn aya wọn.

17. Kó gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹlu rẹ jáde, àwọn ẹyẹ, ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí wọ́n lè máa bímọ lémọ, kí wọ́n sì pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé.”

18. Noa bá jáde kúrò ninu ọkọ̀, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn aya wọn,

19. pẹlu gbogbo àwọn ẹranko, gbogbo àwọn ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati àwọn ẹyẹ. Gbogbo àwọn ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ patapata ni wọ́n bá Noa jáde kúrò ninu ọkọ̀.

20. Noa tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹran ati àwọn ẹyẹ tí wọ́n mọ́, ó fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ náà.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 8