Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 7:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí ó yá OLUWA sọ fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ, nítorí pé ìwọ nìkan ni o jẹ́ olódodo sí mi ní gbogbo ayé.

2. Ninu gbogbo ẹran tí ó bá jẹ́ mímọ́, mú wọn ní takọ-tabo, meje meje, ṣugbọn ninu gbogbo ẹran tí kò bá jẹ́ mímọ́, mú akọ kan ati abo kan.

3. Mú takọ-tabo meje meje ninu àwọn ẹyẹ, kí irú wọn lè wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé.

4. Nítorí pé ọjọ́ meje ló kù tí n óo bẹ̀rẹ̀ sí rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí mo dá ni yóo sì parun lórí ilẹ̀ ayé.”

5. Noa bá ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un.

6. Noa jẹ́ ẹni ẹgbẹta (600) ọdún nígbà tí ìkún omi bo ilẹ̀ ayé.

7. Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati aya rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu aya wọn, láti sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìkún omi.

8. Gbogbo ẹran ati àwọn tí wọ́n mọ́ ati àwọn tí wọn kò mọ́, àwọn ẹyẹ ati gbogbo ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀,

9. ní meji meji, àtakọ àtabo, gbogbo wọn bá Noa wọ inú ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún Noa.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 7