Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 6:14-19 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nítorí náà, fi igi goferi kan ọkọ̀ ojú omi fún ara rẹ. Ṣe ọpọlọpọ yàrá sinu rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà kùn ún ninu ati lóde.

15. Bí o óo ti kan ọkọ̀ náà nìyí: kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọọdunrun (300) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ.

16. Kan òrùlé sí orí ọkọ̀ náà, ṣugbọn fi ààyè sílẹ̀ láàrin orí rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, tí yóo jẹ́ ìwọ̀n igbọnwọ kan. Kí o kan ọkọ̀ náà ní ìpele mẹta, kí o sì ṣe ẹnu ọ̀nà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

17. N óo jẹ́ kí ìkún omi bo gbogbo ayé, yóo pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà láyé ni yóo kú.

18. Ṣugbọn n óo bá ọ dá majẹmu, o óo wọ inú ọkọ̀ náà, ìwọ pẹlu aya rẹ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn aya wọn.

19. Kí o sì mú meji meji ninu gbogbo ohun alààyè, kí wọ́n lè wà láàyè pẹlu rẹ, takọ-tabo ni kí o mú wọn.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 6