Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 50:16-26 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Wọ́n bá ranṣẹ sí Josẹfu pé, “Baba rẹ ti fi àṣẹ yìí lélẹ̀ kí ó tó kú pé,

17. ‘Ẹ sọ fún Josẹfu pé, dárí àṣìṣe ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn arakunrin rẹ jì wọ́n, nítorí wọ́n ṣe ibi sí ọ.’ ” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Josẹfu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún.

18. Àwọn arakunrin rẹ̀ náà sì wá, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ní, “Wò ó, a di ẹrú rẹ.”

19. Ṣugbọn Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, èmi kì í ṣe Ọlọrun.

20. Ní tiyín, ẹ gbèrò ibi sí mi, ṣugbọn Ọlọrun yí i pada sí rere, kí ó lè dá ẹ̀mí ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n wà láàyè lónìí sí.

21. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù, n óo máa tọ́jú ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, tí ó sì dá wọn lọ́kànle.

22. Josẹfu sì ń gbé ilẹ̀ Ijipti, òun ati ìdílé baba rẹ̀, ó gbé aadọfa (110) ọdún láyé.

23. Josẹfu rí ìran kẹta ninu àwọn ọmọ Efuraimu. Àwọn ọmọ tí Makiri ọmọ Manase bí, ọwọ́ Josẹfu ni ó bí wọn sí pẹlu.

24. Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Àtikú mi kù sí dẹ̀dẹ̀, ṣugbọn Ọlọrun yóo máa tọ́jú yín, yóo sì mu yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu.”

25. Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra fún un pé, nígbà tí Ọlọrun bá mú wọn pada sí ilẹ̀ Kenaani, wọn yóo kó egungun òun lọ́wọ́ lọ.

26. Josẹfu kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n fi òògùn tọ́jú òkú rẹ̀ kí ó má baà bàjẹ́, wọ́n sì tẹ́ ẹ sinu pósí ní ilẹ̀ Ijipti.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 50