Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 50:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Josẹfu dojúbo òkú baba rẹ̀ lójú, ó sọkún, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

2. Lẹ́yìn náà, Josẹfu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń ṣiṣẹ́ ìṣègùn pé kí wọ́n fi òògùn tí wọ́n fi máa ń tọ́jú òkú, tí kì í fíí bàjẹ́, tọ́jú òkú baba òun. Wọ́n fi òògùn yìí tọ́jú òkú Jakọbu.

3. Ogoji ọjọ́ gbáko ni àwọn oníṣègùn máa fi ń tọ́jú irú òkú bẹ́ẹ̀. Àwọn ará Ijipti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún aadọrin ọjọ́.

4. Nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Josẹfu sọ fún àwọn ará ilé Farao pé, “Ẹ jọ̀wọ́, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ bá mi sọ fún Farao pé,

5. baba mi mú mi búra nígbà tí àtikú rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, pé, ‘Nígbà tí mo bá kú, ninu ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani, ni kí ẹ sin mí sí.’ Nítorí náà, kí Farao jọ̀wọ́, fún mi láàyè kí n lọ sin òkú baba mi, n óo sì tún pada wá.”

6. Farao dáhùn, ó ní, “Lọ sin òkú baba rẹ gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún un.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 50