Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 48:19-22 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ṣugbọn baba rẹ̀ kọ̀, ó ní, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀, òun náà yóo di eniyan, yóo sì di alágbára, ṣugbọn sibẹsibẹ àbúrò rẹ̀ yóo jù ú lọ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ yóo sì di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè.”

20. Ó bá súre fún wọn ní ọjọ́ náà, ó ní,“Orúkọ yín ni Israẹli yóo fi máa súre fún eniyan,wọn yóo máa súre pé,‘Kí Ọlọrun kẹ́ ọ bí ó ti kẹ́ Efuraimu ati Manase.’ ”Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi Efuraimu ṣáájú Manase.

21. Nígbà náà ni Israẹli sọ fún Josẹfu pé, “Àkókò ikú mi súnmọ́ etílé, ṣugbọn Ọlọrun yóo wà pẹlu rẹ, yóo sì mú ọ pada sí ilẹ̀ baba rẹ.

22. Dípò kí n fún àwọn arakunrin rẹ ní Ṣekemu, tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkè, níbi tí mo jagun gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori, ìwọ ni mo fún.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 48