Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 45:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé mi dé ìhín, Ọlọrun ni, ó sì ti fi mí ṣe baba fún Farao, ati oluwa ninu gbogbo ilé rẹ̀ ati alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

9. “Ẹ ṣe kíá, ẹ wá lọ sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ wí fún un pé, Josẹfu ọmọ rẹ̀ wí pé, Ọlọrun ti fi òun ṣe olórí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, ẹ ní mo ní kí ó máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi kíákíá.

10. Ẹ sọ fún un pé mo sọ pé kí ó wá máa gbé ní ilẹ̀ Goṣeni nítòsí mi, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ati agbo mààlúù rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní.

11. N óo máa tọ́jú rẹ̀ níbẹ̀, nítorí pé ó tún ku ọdún marun-un gbáko kí ìyàn yìí tó kásẹ̀ nílẹ̀, kí òun ati ìdílé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ má baà di aláìní.

12. “Ẹ̀yin pàápàá fi ojú rí i, Bẹnjamini arakunrin mi náà sì rí i pẹlu pé èmi gan-an ni mò ń ba yín sọ̀rọ̀.

13. Ẹ níláti sọ fún baba mi nípa gbogbo ògo mi ní Ijipti, ati gbogbo ohun tí ẹ ti rí. Ẹ tètè yára mú baba mi wá bá mi níhìn-ín.”

14. Ó bá rọ̀ mọ́ Bẹnjamini arakunrin rẹ̀ lọ́rùn, ó sì bú sẹ́kún, bí Bẹnjamini náà ti rọ̀ mọ́ ọn, ni òun náà bú sẹ́kún.

15. Josẹfu bá fi ẹnu ko àwọn arakunrin rẹ̀ lẹ́nu lọ́kọ̀ọ̀kan, ó sì sọkún, lẹ́yìn náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀.

16. Nígbà tí gbogbo ìdílé Farao gbọ́ pé àwọn arakunrin Josẹfu dé, inú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ dùn pupọ.

17. Farao sọ fún Josẹfu pé kí ó sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ kí wọ́n múra, kí wọ́n di ẹrù ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, kí wọ́n tètè pada lọ sí Kenaani,

18. kí wọ́n sì lọ mú baba rẹ̀ ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ wá sọ́dọ̀ òun. Ó ní òun óo fún un ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, wọn yóo sì jẹ àjẹyó ninu ilẹ̀ náà.

19. Ó ní kí Josẹfu pàṣẹ fún wọn pẹlu kí wọ́n kó kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi kó àwọn ọmọde ati àwọn obinrin, kí baba wọn náà sì máa bá wọn bọ̀.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 45