Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 43:11-26 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Israẹli, baba wọn bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dára, báyìí ni kí ẹ ṣe, ẹ dì ninu àwọn èso tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ yìí sinu àpò yín, kí ẹ gbé e lọ fún ọkunrin náà. Ẹ mú ìpara díẹ̀, oyin díẹ̀, turari díẹ̀ ati òjíá díẹ̀, ẹ mú èso pistakio ati èso alimọndi pẹlu.

12. Ìlọ́po meji owó ọjà tí ẹ óo rà ni kí ẹ mú lọ́wọ́, ẹ mú owó tí ó wà lẹ́nu àpò yín níjelòó lọ́wọ́ pẹlu, bóyá wọ́n gbàgbé ni.

13. Ẹ mú arakunrin yín náà lọ́wọ́, kí ẹ sì tọ ọkunrin náà lọ.

14. Kí Ọlọrun Olodumare jẹ́ kí ọkunrin náà ṣàánú yín, kí ó sì dá arakunrin yín kan yòókù ati Bẹnjamini pada. Bí mo bá tilẹ̀ wá ṣòfò àwọn ọmọ mi nígbà náà, n óo gbà pé mo ṣòfò wọn.”

15. Àwọn ọkunrin náà bá gbé ẹ̀bùn náà, wọ́n sì mú ìlọ́po meji owó tí wọ́n nílò, ati Bẹnjamini, wọ́n lọ siwaju Josẹfu ní Ijipti.

16. Nígbà tí Josẹfu rí Bẹnjamini pẹlu wọn, ó sọ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Mú àwọn ọkunrin wọnyi wọlé, pa ẹran kan kí o sì sè é, nítorí wọn yóo bá mi jẹun lọ́sàn-án yìí.”

17. Ọkunrin náà ṣe bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un, ó sì mú àwọn ọkunrin náà wọ ilé Josẹfu lọ.

18. Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà wọ́n nígbà tí Josẹfu mú wọn wọ ilé rẹ̀, wọ́n ń wí fún ara wọn pé, “Nítorí owó tí wọ́n fi sí ẹnu àpò wa níjelòó ni wọ́n fi kó wa wọlé, kí ó lè rí ẹ̀sùn kà sí wa lẹ́sẹ̀, kí ó lè fi wá ṣe ẹrú, kí ó sì kó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.”

19. Wọ́n bá tọ alabojuto ilé Josẹfu lọ lẹ́nu ọ̀nà,

20. wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, a ti kọ́kọ́ wá ra oúnjẹ níhìn-ín nígbà kan.

21. Nígbà tí à ń pada lọ tí a dé ibi tí a fẹ́ sùn, a tú àpò wa, olukuluku wa bá owó tirẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀, kò sí ti ẹni tí ó dín rárá, a mú owó náà lọ́wọ́ báyìí.

22. A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ pẹlu láti ra oúnjẹ. A kò mọ ẹni tí ó dá owó wa pada sinu àpò wa.”

23. Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ fọkàn yín balẹ̀, ẹ má bẹ̀rù, ó níláti jẹ́ pé Ọlọrun yín ati ti baba yín ni ó fi owó náà sinu àpò yín fun yín, mo gba owó lọ́wọ́ yín.” Ó bá mú Simeoni jáde sí wọn.

24. Ọkunrin náà mú wọn wọ inú ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi, wọ́n fọ ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní oúnjẹ.

25. Lẹ́yìn náà wọ́n tọ́jú ẹ̀bùn Josẹfu sílẹ̀ di ìgbà tí yóo dé lọ́sàn-án, nítorí wọ́n gbọ́ pé ibẹ̀ ni wọn yóo ti jẹun.

26. Nígbà tí Josẹfu wọlé, wọ́n mú ẹ̀bùn tí wọ́n mú bọ̀ fún un wọlé tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n sì wólẹ̀ fún un, wọ́n dojúbolẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 43