Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 43:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ìyàn tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani ṣá túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni.

2. Nígbà tí wọ́n jẹ ọkà tí wọ́n rà ní Ijipti tán, baba wọn pè wọ́n, ó ní, “Ẹ tún wá lọ ra oúnjẹ díẹ̀ sí i.”

3. Ṣugbọn Juda dá a lóhùn, ó ní, “Ọkunrin náà kìlọ̀ fún wa gidigidi pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé a mú arakunrin wa lọ́wọ́.

4. Bí o bá jẹ́ kí arakunrin wa bá wa lọ, a óo lọ ra oúnjẹ wá fún ọ,

5. ṣugbọn bí o kò bá jẹ́ kí ó bá wa lọ, a kò ní lọ, nítorí pé ọkunrin náà tẹnumọ́ ọn fún wa pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé arakunrin wa bá wa wá.”

6. Israẹli ní, “Irú ọ̀ràn ńlá wo ni ẹ tún dá sí mi lọ́rùn yìí, tí ẹ lọ sọ fún ọkunrin náà pé ẹ ní arakunrin mìíràn?”

7. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí ohun tí ọkunrin náà kò bi wá tán nípa ará ati ẹbí wa, ó ní, ‘Ǹjẹ́ baba yín wà láàyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arakunrin mìíràn?’ Àwọn ìbéèrè tí ó ń bèèrè ni ó mú kí á sọ ohun tí a sọ fún un. Báwo ni a ṣe lè mọ̀ pé yóo sọ pé kí á mú àbúrò wa wá?”

8. Juda bá sọ fún Israẹli, ó ní, “Fa ọmọ náà lé mi lọ́wọ́, a óo sì lọ kí á lè wà láàyè, kí ebi má baà pa ẹnikẹ́ni kú ninu wa, ati àwọn ọmọ wa kéékèèké.

9. N óo dúró fún ọmọ náà, ọwọ́ mi ni kí o ti bèèrè rẹ̀. Bí n kò bá mú un pada, kí n sì fà á lé ọ lọ́wọ́, da ẹ̀bi rẹ̀ lé mi lórí títí lae,

10. nítorí pé bí a kò bá fi ìrìn àjò yìí falẹ̀ ni, à bá ti lọ, à bá sì ti dé, bí ẹẹmeji.”

11. Israẹli, baba wọn bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dára, báyìí ni kí ẹ ṣe, ẹ dì ninu àwọn èso tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ yìí sinu àpò yín, kí ẹ gbé e lọ fún ọkunrin náà. Ẹ mú ìpara díẹ̀, oyin díẹ̀, turari díẹ̀ ati òjíá díẹ̀, ẹ mú èso pistakio ati èso alimọndi pẹlu.

12. Ìlọ́po meji owó ọjà tí ẹ óo rà ni kí ẹ mú lọ́wọ́, ẹ mú owó tí ó wà lẹ́nu àpò yín níjelòó lọ́wọ́ pẹlu, bóyá wọ́n gbàgbé ni.

13. Ẹ mú arakunrin yín náà lọ́wọ́, kí ẹ sì tọ ọkunrin náà lọ.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 43