Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 39:16-23 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Obinrin náà bá fi ẹ̀wù rẹ̀ sọ́dọ̀ títí tí ọ̀gá rẹ̀ fi wọlé dé.

17. Nígbà tí ó dé, obinrin yìí sọ ohun kan náà fún un, ó ní, “Ẹrú ará Heberu tí o mú wá sí ààrin wa, ni ó déédé wọlé tọ̀ mí wá láti fi ẹ̀gbin lọ̀ mí,

18. ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé mo pariwo, ó ju ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́, ó sá jáde.”

19. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ẹrú rẹ ti ṣe sí mi nìyí” inú bí i gidigidi,

20. ó sì sọ Josẹfu sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ibi tí wọn ń ti àwọn tí ọba bá sọ sí ẹ̀wọ̀n mọ́ ni wọ́n tì í mọ́.

21. Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ hàn sí i, ó jẹ́ kí ó bá ojurere alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pàdé.

22. Alabojuto náà fi Josẹfu ṣe olùdarí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ẹ̀wọ̀n, ohunkohun tí Josẹfu bá sọ, ni wọ́n ń ṣe.

23. Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kì í fi nǹkan lé Josẹfu lọ́wọ́ kí ó tún bìkítà fún un mọ́, nítorí pé OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ohunkohun tí ó bá ṣe, OLUWA ń jẹ́ kí ó yọrí sí rere.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 39