Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 38:19-30 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ó dìde, ó bá tirẹ̀ lọ, ó ṣí ìbòjú rẹ̀ kúrò, ó sì tún wọ aṣọ ọ̀fọ̀ rẹ̀.

20. Juda fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Adulamu, sí Tamari, kí ó le bá a gba àwọn ohun tí ó fi dógò lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò bá a níbẹ̀ mọ́.

21. Ó bi àwọn ọkunrin kan, ará ìlú náà pé, “Níbo ni obinrin aṣẹ́wó tí ó máa ń jókòó ní gbangba lẹ́bàá ọ̀nà Enaimu yìí wà?”Wọ́n dáhùn pé, “Kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan ní àdúgbò yìí.”

22. Ọ̀rẹ́ Juda bá pada tọ̀ ọ́ lọ, ó ní òun kò rí i, ati pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀ sọ pé kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan níbẹ̀.

23. Juda dá a lóhùn, ó ní, “Má wulẹ̀ wá a kiri mọ́, kí àwọn eniyan má baà máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. Jẹ́ kí ó ṣe àwọn nǹkan ọwọ́ rẹ̀ bí ó bá ti fẹ́, mo ṣá fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ tí mo ṣèlérí ranṣẹ, o kò rí i ni.”

24. Lẹ́yìn bí oṣù mẹta sí i, ẹnìkan wá sọ fún Juda pé, “Wò ó! Iṣẹ́ aṣẹ́wó ni Tamari, opó ọmọ rẹ ń ṣe, ó sì ti lóyún.”Juda bá dáhùn, ó ní, “Ẹ lọ mú un wá kí wọ́n dáná sun ún.”

25. Nígbà tí wọ́n mú un dé, ó ranṣẹ sí baba ọkọ rẹ̀, ó ní, “Ẹni tí ó ni àwọn nǹkan wọnyi ni ó fún mi lóyún. Jọ̀wọ́ yẹ̀ wọ́n wò, kí o mọ ẹni tí ó ni èdìdì yìí pẹlu okùn rẹ̀, ati ọ̀pá yìí.”

26. Juda yẹ̀ wọ́n wò, ó sì mọ̀ wọ́n, ó ní, “O ṣe olóòótọ́ jù mí lọ, èmi ni mo jẹ̀bi nítorí pé n kò ṣú ọ lópó fún Ṣela, ọmọ mi.” Kò sì bá a lòpọ̀ mọ́.

27. Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, wọ́n rí i pé ìbejì ni ó wà ninu rẹ̀.

28. Bí ó ti ń rọbí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ náà yọ ọwọ́ jáde, ẹni tí ń bá a gbẹ̀bí bá so òwú pupa mọ́ ọn lọ́wọ́, ó ní “Èyí tí ó kọ́ jáde nìyí.”

29. Ṣugbọn bí ọmọ náà ti fa ọwọ́ rẹ̀ pada, arakunrin rẹ̀ bá jáde. Agbẹ̀bí náà bá wí pé, “Ṣé bí o ti fẹ́ rìn nìyí, ó hàn lára rẹ.” Ó bá sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi.

30. Láìpẹ́ arakunrin rẹ̀ náà wálẹ̀, pẹlu òwú pupa tí wọ́n so mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá sọ ọ́ ní Sera.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 38