Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 38:1-17 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà ni Juda bá fi àwọn arakunrin rẹ̀ sílẹ̀, ó kó lọ sí ọ̀dọ̀ ará Adulamu kan tí wọn ń pè ní Hira.

2. Níbẹ̀ ni Juda ti rí ọmọbinrin ará Kenaani kan, tí baba rẹ̀ ń jẹ́ Ṣua, ó gbé e níyàwó, ó sì bá a lòpọ̀.

3. Ó lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, Juda sọ ọmọ náà ní Eri.

4. Ó tún lóyún, ó bí ọmọkunrin keji, ó sọ ọ́ ní Onani.

5. Ó tún lóyún mìíràn, ó tún bí ọkunrin bákan náà, ó bá sọ ọmọ náà ní Ṣela. Ìlú Kẹsibu ni ó wà nígbà tí ó bí ọmọ náà.

6. Juda fẹ́ aya fún Eri, àkọ́bí rẹ̀. Orúkọ obinrin náà ni Tamari.

7. Ìwà Eri burú tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun fi pa á.

8. Juda bá pe Onani, ó ní, “Ṣú iyawo arakunrin rẹ lópó kí o sì bá a lòpọ̀, kí ó lè bímọ fún arakunrin rẹ.”

9. Ṣugbọn Onani mọ̀ pé ọmọ tí opó náà bá bí kò ní jẹ́ ti òun, nítorí náà, nígbàkúùgbà tí ó bá ń bá opó yìí lòpọ̀, yóo sì da nǹkan ọkunrin rẹ̀ sílẹ̀, kí ó má baà bí ọmọ tí yóo rọ́pò arakunrin rẹ̀.

10. Ohun tí Onani ń ṣe yìí kò dùn mọ́ Ọlọrun ninu, Ọlọrun bá pa òun náà.

11. Juda bá sọ fún Tamari opó ọmọ rẹ̀ pé, “Wá pada sí ilé baba rẹ kí o lọ máa ṣe opó níbẹ̀ títí tí Ṣela, ọmọ mi yóo fi dàgbà.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí Juda sọ yìí kò dé inú rẹ̀ nítorí ẹ̀rù ń bà á pé kí Ṣela náà má kú bí àwọn arakunrin rẹ̀, Tamari bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀.

12. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya Juda, tíí ṣe ọmọ Ṣua kú. Nígbà tí Juda ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, òun ati Hira ará Adulamu, ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá múra, wọ́n lọ sí Timna lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń rẹ́ irun aguntan Juda.

13. Àwọn kan lọ sọ fún Tamari pé baba ọkọ rẹ̀ ń lọ sí Timna láti rẹ́ irun aguntan rẹ̀.

14. Tamari bá bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára, ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ó wọ aṣọ tí ó dára, ó bá jókòó lẹ́nu bodè Enaimu tí ó wà lọ́nà Timna; nítorí ó mọ̀ pé Ṣela ti dàgbà, wọn kò sì ṣú òun lópó fún un.

15. Nígbà tí Juda rí Tamari tí ó fi aṣọ bojú, ó rò pé aṣẹ́wó ni.

16. Ó tọ̀ ọ́ lọ níbi tí ó jókòó sí lẹ́bàá ọ̀nà, ó ní, “Wá, jẹ́ kí n bá ọ lòpọ̀,” kò mọ̀ pé opó ọmọ òun ni. Tamari dá a lóhùn, ó ní: “Kí ni o óo fún mi tí mo bá gbà fún ọ?”

17. Juda dáhùn, ó ní, “N óo fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ kan ranṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran mi.” Tamari ní, “O níláti fi nǹkankan dógò títí tí o óo fi fi ọmọ ewúrẹ́ náà ranṣẹ.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 38