Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 37:30-36 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Ó pada lọ bá àwọn arakunrin rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ọmọ náà kò sí níbẹ̀? Mo gbé! Ibo ni n óo yà sí?”

31. Wọ́n bá mú ọmọ ewúrẹ́ kan ninu agbo, wọ́n pa á, wọ́n sì ti ẹ̀wù Josẹfu bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

32. Wọ́n bá fi ẹ̀wù aláràbarà náà ranṣẹ sí baba wọn, wọ́n ní, “Ohun tí a rí nìyí. Wò ó wò, bóyá ẹ̀wù ọmọ rẹ ni, tabi òun kọ́.”

33. Jakọbu yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì wí pé, “Ẹ̀wù ọmọ mi ni, ẹranko burúkú kan ti pa á, dájúdájú, ẹranko náà ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.”

34. Jakọbu bá fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọpọlọpọ ọjọ́.

35. Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin lọ láti tù ú ninu, ṣugbọn ó kọ̀, kò gba ìpẹ̀, ó ní, “Ninu ọ̀fọ̀ ni n óo wọ inú ibojì lọ bá ọmọ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni baba rẹ̀ sọkún rẹ̀.

36. Àwọn ará Midiani tí wọ́n ra Josẹfu tà á fún Pọtifari, ará Ijipti, ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao. Pọtifari yìí ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 37